RCCG YORUBA SUNDAY SCHOOL TEACHER'S MANUALỌJỌ́ KẸRIN OSÙ KẸJỌ, ỌDÚN 2024Ẹ̀KỌ́ KỌKÀNDÍNLÁÀDỌ́TA (49)

AKORI: ÀKÓKÒ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ

ÀDÚRÀ ÌBẸ̀RẸ̀: Baba alágbára jùlọ, jọ̀wọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti dúro dè ọ́ títí di òpin lórúkọ Jésù.

ÌMỌ̀ ÀTẸ̀HÌNWÁ: Kí olùkọ́ fún akẹ́kọ̀ọ́ láyè láti ṣe àtúnyẹ̀wò ẹ̀kọ́ ti ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

BÍBÉLÌ KÍKÀ: Máàkù 13:19-26.
[19] Nitori ọjọ wọnni, yio jẹ ọjọ ipọnju irú eyi ti kò si lati igba ọjọ ìwa ti Ọlọrun da, titi fi di akokò yi, irú rẹ̀ ki yio si si. [20] Bi ko si ṣe bi Oluwa ti ke ọjọ wọnni kuru, kò si ẹda ti iba le là: ṣugbọn nitoriti awọn ayanfẹ ti o ti yàn, o ti ke ọjọ wọnni kuru. [21] Nitorina bi ẹnikan ba wi fun nyin pe, wo o, Kristi mbẹ nihinyi; tabi, wo o, o mbẹ lọ́hun; ẹ máṣe gbà a gbọ́: [22] Nitori awọn eke Kristi, ati awọn eke woli yio dide, nwọn o si fi àmi ati ohun iyanu hàn, tobẹ̃ bi o ṣe iṣe, nwọn iba tàn awọn ayanfẹ pãpã. [23] Ṣugbọn ẹ kiyesara: wo o, mo sọ ohun gbogbo fun nyin tẹlẹ. [24] Ṣugbọn li ọjọ wọnni, lẹhin ipọnju na, õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọle rẹ̀ hàn; [25] Awọn irawọ oju ọrun yio já silẹ̀, ati agbara ti mbẹ li ọrun li a o si mì titi. [26] Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara nla ati ogo.

ẸSẸ̀ ÀKỌ́SÓRÍ: “Nítorí ìpọ́njú ńlá yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ láti ìgbà ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ ayé wá títí di ìsinsin yìí irú rẹ̀ kì yóò sì ṣí.” Mátíù 24:21.

ÀFIHÀN: Ọ̀rọ̀ náà, ìṣubú ńlá, túmọ̀ sí wàhálà/ìdàmú. Onírúurú ìpọ́njú ni Bíbélì mẹ́nu bà. Àwọn wọ̀nyìí rí ìpọ́njú láti ipasẹ̀ gbígbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run (Mátíù 13:21); ìpọ́njú ní ọ̀nà sí ìjọba ọ̀run (Ìṣe Àpóstélì 14:22); ìpọ́njú nínú ayé ní èyí tí ó wọ́pọ̀ (Jóbù 5:6-7); ìpọ́njú lórí àwọn aṣebi (Rómù 2:9) àti àkókò ìpọ́njú ńlá. Ohun tí ẹ̀kọ́ yìí yóò dá lé lórí ni àkókò ìpọ́njú ńlá. Ìnira, ìkérora, àti àìlera ni àwọn ohun tí àwọn ènìyan yóò kojú ni àkókò ìpọ́njú ńlá láì ṣẹ̀. Kí ni àwọn ohun tí ìpọ́njú ńlá dá lé lórí? Ìgbà wo ni yóò jẹ́? Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni yóò ṣẹlẹ̀ ni àkókò ìpọ́njú ńlá.

ÀKỌSÍLẸ̀ OLÙKỌ
ÌLÉPA Ẹ̀KỌ́: Láti kọ́ nípa ìtumọ̀ àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ àkókò ìpọ́njú ńlá.

ÈRÒǸGBÀ ÌKỌ́NÍ: Ní òpin ẹ̀kọ́ yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò lè:
a) Lóye ìtumọ̀ àkókò ìpọ́njú ńlá.
b) Ṣàwárí àwọn iṣẹ̀lẹ̀ tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìpọ́njú ńlá.

ÈTÒ ÌKỌ́NI: Láti lè ṣe èróngbà òkè yìí, olùkọ́ ní láti:  
a. Fún akẹ́kọ kan ní ànfààní láti ka ẹsẹ̀ àkọ́sórí, sọ Bíbélì kika, ṣe ìdásí nínú ìjíròrò ṣe isẹ́ ṣíṣe ilé ìkẹ́kọ̀ọ́ àti iṣẹ́ àmúrelé.
b. Fún igbákejì olùkọ́ ní ààyè láti ṣe àbójútó, kíláàsì, àkọsílẹ̀ wíwá àti iṣẹ́ àmúrelé.
d. Kọ àwọn ìlànà ẹ̀kọ́ ṣe àkójopọ̀ ìkádìí, yannàná ẹ̀kọ́ àti pẹ̀lú fi iṣẹ́ àmúrelé fún akẹ́kọ̀ọ́ ní síṣe.

ÀTÚNYẸ̀WÒ BÍBẸ́LÌ KÍKÀ: Máàkù 13:19-26.
Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni yóò ṣẹlẹ̀ ni àkókò ìpọ́njú ńlá.
i. Ìjìya tí ó ṣọ̀wán. Mák 13:19.
ii. Ìdàrúdàpọ̀ lórí ibi ti krístì wà Mák 13:21. 
iii. Krístì àti àwọn wòólì èké yóò dìde. ẹsẹ̀ 22.
iv. Iṣẹ́ ìyanu èké àti àwọn ohun ẹ̀tàn. ẹsẹ̀ 22.
Kí olùkọ́ ṣàfàyọ èyíkéyìí ohun márùn-ún mìíràn tí ó lè ṣẹlẹ̀ láti lè mọ àkókò ìpọ́njú nlá nínú ibi kíkà náà.
i. --------------------------------------------------------------
ii. ---------------------------------------------------------------
iii. -------------------------------------------------------------
iv. -------------------------------------------------------------
v. ---------------------------------------------------------------

ỌGBỌ́N ÌKỌ́NI: Kí olùkọ́ lo ọgbọ́n ìkọ́niọlọ́rọ̀ geere.

LÍLÒ ÀKÓKÒ: Kí olùkọ́ lo àkokò ti a yàn fún kíkọ́ ìlànà ẹ̀kọ́ méjèèjì.

ÀWỌN ÌLÀNÀ Ẹ̀KỌ́
1.NÍNÍ ÒYE ÀKÓKÒ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ
2. ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ TÍ YÓÒ ṢẸLẸ̀ NÍ ÀKÓKÒ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ

1. NÍNÍ ÒYE ÀKÓKÒ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ
i. Àkókò ìpọ́njú ńlá ni a tún ń pè ni àkókò (Orílẹ̀-èdè Ísrẹ́lì) ìpọ́njú Jákọ́bù (Jer 30:7). 
ii. Àwọn ọmọ Júù tí wọn kò gbàgbọ́, àwọn tí wọn kòyì tíì di ẹni-ìgbàlà tàbí àwọn apẹ̀yìndà tí wọn kìí ṣe Júù ni yóò kojú àkókò ìpọ́njú ńlá náà. 
iii. Yóò bẹ̀ẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn ìgbàsókè àwọn àyànfẹ́ àti ní àkókò tí àwọn aṣodìsí-krístì yóò dé, ọkùnrin náà ẹni ẹ̀ṣẹ̀ (2Tẹsa 2:3-7).
iv. Àkókò ìpọ́njú ńlá yóò jẹ́ “àádọ́rin ọ̀sẹ̀” tí ó túmọ̀ sí, ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn nínú àádọ́rin ọ̀sẹ̀ Dáníẹ́lì. 
v. Àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà ní ipele mẹ́ta: osẹ̀ méje àkọ́kọ́, ọ̀sẹ̀ ọ̀gọ́ta tí ó tẹ̀le, àti ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn. 
vi. Ọjọ́ méje ni ó wà nínú ọ̀sẹ̀ kan. Ọjọ́ kan nínú ọ̀sẹ̀ dúró fún ọdún kan. Gbogbo àkókò yìí sì jẹ́ ọdún méje (Dán 9:20-27).
vii. Ìdajì àkọ́kọ́ nínú ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn (Ọdún mẹ́ta àti àbọ̀ àkọ́kọ́) ni ìwà ìṣòdìsí-krístì yóò bẹ̀rẹ̀ sí di ohun àfojúrí, nígbà yìí ni yóò ní májẹ̀mú pẹ̀lú Ísrẹ́lì (Dán 9:27). 
viii. Ìdajì ọ̀sẹ̀ tí ó gbẹ̀yìn (ọdún mẹ́ta àbọ̀ tí ó gbẹ̀yìn) yóò jẹ́ àkókò wàhálà àìròtẹ́lẹ̀. “Nínú ọ̀sẹ̀ náà” àwọn aṣòdìsí-krístì yóò yóò ba májẹ̀mú tí wọ́n ní pẹ̀lú Ísrẹ́lì jẹ́ tí wọ́n á sì máa ṣe “àwọn ohun ìrírà ti yóò yọrí sí ìparun” nínú tẹ́mpìlì (Dán 11:36; Mát 24:15, 16).
ix. ọdún mẹ́ta àbọ̀ tí ó gbẹ̀yìn tí àkókò ìpọ́njú ńlá ní àpapọ̀ rẹ̀ yóò jẹ́ ìgbà tí Krístì yóò fi jọba (Mák 13:24-26; 2 Tẹsa 2:8). 

IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KÍNNÍ: Kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́nu ba àwọn ohun tí ó ṣe kókó nípa àkókò ìpọ́njú ńlá gẹ́gẹ́ bí ó ti wà nínú liana ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́.

2. ÀWỌN ÌṢẸ̀LẸ̀ TÍ YÓÒ ṢẸLẸ̀ NÍ ÀKÓKÒ ÌPỌ́NJÚ ŃLÁ
Àwọn ohun búbúru ni yóò ṣẹ̀lẹ̀ ní àkókò ìpọ́njú ńlá. Àwọn náà ni:
1. Pípọ́n àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n pàdánù ìgbàsókè lójú (Mát 24:21-22).
2. Ẹ̀sìn ẹ̀tàn yóò wà ní gbogbo àgbáyé (Mát 24:24-28). 
3. Ètò ọrọ̀-ajé gbogbo àgbéyé yóò ní ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀, ní èyí tí ó jẹ́ pé àwọn tí wọ́n ba
 Gba àmì ẹranko búburú náà ni yóò lè dúnàá-dúrà (Ìfi 13:17, 18).
4. Ọ̀pọ̀ ìwà àìṣòdodo àti àwọn ohun ìríra ni yóò kún inú ẹ̀sìn (2Tẹsa 2:3-4, 10). 
5. Ogunlọ́gọ̀ àdànwó ní yóò kún gbogbo ayé nígbà náà (Ìfi 3:10).       

IṢẸ́ ṢÍṢE KÍLÁÀSÌ KEJÌ: Mẹ́nu ba àwọn ohun ìdámọ̀ àkókò ìpọ́njú ńlá gẹ́gẹ́ bí ó tí wà nínú liana ẹ̀kọ́ kejì.

ÀKOJỌPỌ̀: Àwọn tí wọ́n gba Krístì ní olúwa àti olùgbàlà wọn tí wọn sì pa ara wọn mọ́ ní mímọ́ títí ìgbàsókè yóò fi dé, ní a yóò gbà kúrò nínú (nípasẹ̀ ìgbàsókè) ewu àkókò ìpọ́njú ńlá ìgbà ìkẹyìn náà. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn apẹ̀yìndà ni wọn yóò kojú ewu àkókò ìpọ́njú ńlá náà. Àyànfẹ́, ǹjẹ́ ìwọ́ ti di ẹni ìgbàlà ní tòótọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Ṣe àyẹ̀wó ara rẹ lónìí kí ó sì dá ọ lójú!

ÌPARÍ: Àwọn tí wọ́n gba Krístì ní olúwa àti olùgbàlà wọn tí wọn sì pa ara wọn mọ́ ní mímọ́ títí ìgbàsókè yóò fi dé, ní a yóò gbà kúrò nínú (nípasẹ̀ ìgbàsókè) ewu àkókò ìpọ́njú ńlá ìgbà ìkẹyìn náà. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti àwọn apẹ̀yìndà ni wọn yóò kojú ewu àkókò ìpọ́njú ńlá náà. Àyànfẹ́, ǹjẹ́ ìwọ́ ti di ẹni ìgbàlà ní tòótọ́ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ bí? Ṣe àyẹ̀wó ara rẹ lónìí kí ó sì dá ọ lójú!

ÌBÉÈRÈ
* Dárúkọ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí a óò fí mọ àkókò ìpọ́njú ńlá.
* Kí ni ọ̀nà àbáyọ sí àkókò ìpọ́njú ńlá?

ÌYÀNNÀNÁ: Báwo ní ìgbà àti àkókò ìpọ́njú ńlá yóò ti ri? 

ÀDÚRÀ ÌPARÍ: Baba alágbára jùlọ, jọ̀wọ́ má jẹ́ kí n kópa nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ibi tí yóò ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìpọ́njú ńlá.

ISẸ́ ÀMÚRELÉ: Dárúkọ àwọn ohun mẹ́wàá tí ó lè ṣẹlẹ̀ ní àkókò ìpọ́njú ńlá. (Máàkì Mẹ́wàá).

Comments

Popular posts from this blog

BECOMING A LIVING SACRIFICE

RCCG Sunday School Manual (YAYA & Conventional) - 7 JULY 2024

RCCG SUNDAY SCHOOL MANUALY.A.Y.A. EDITIONLESSON FORTY-SEVENDATE: SUNDAY 21ST JULY 2024